Pọ́n-na: Àtiwáyé Àti Ìṣẹ̀dá Rẹ̀ Nínú Ewì Yorùbá

Authors

  • Monísọ́lá Rónkẹ́ FÁLADÉ National Open University of Nigeria Federal Capital Territory, Abuja, Nigeria Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20757721

Keywords:

Pọ́n-na, Ewì Yorùbá, Àtiwáyé, Ìṣẹ̀dá, Tíọ́rì Ìfojú-Ààtò-Wo-Iṣẹ́-Lítíréṣọ̀.

Abstract

Ọ̀rọ̀, tàbí gbólóhùn tí ó bá ti ní ju ìtúmọ̀ kan lọ ni a ń pè ni pọ́n-na. Kò sí èdè ti pọ́n-na yọ sílẹ̀. O jẹ́ ọ̀kan lára àbùdá gbogbo èdè lágbàyéé. Gẹ́gẹ́ bí àbùdá iṣẹ́-ọnà, a máa ń rí pọ́n-na nínú ewì ju àwọn iṣẹ́-ọnà yóòkù lọ. Fún ìdí èyí, pépà yìí ṣe ìwádìí àtiwáyé pọ́n-na nínú ewì Yorùbá àti ìṣẹ̀dá rẹ̀ bí àwọn akéwì ṣe ń ṣàmúlò rẹ̀ nínú ewì wọn. Kí ìwádìí wa lè múná dóko, a ó lo ìwé ewì mẹ́rìnlá ti àwọn akéwì mẹ́sàn-án kọ fún pépa yìí. Tíọ́rì pọ́n-na tí william Empson ṣe agbátẹrù rẹ̀ tí a ṣe àfàyọ láti inú Tíọ́rì Ìfojú-Ààtò-Wo-Iṣẹ́-Lítíréṣọ̀ tí àwọn oníṣẹ́ ọ̀rọ̀ lámèyítọ́ pè ní ìlànà titun (New Criticism) ni a ó lò fún ìtúpalẹ̀ àti àlàyé àwọn ewì yìí. Pépà yi ṣe àkíyèsí pe pọ́n-na lè jẹ jáde láti ara àkànlò èdè, àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́, fẹ̀dádọ́gba, polisẹ̀míkì, àwọn ọ̀rọ̀ to kọ́wọ̀ọ́ rìn papọ̀, àmì àti ẹ̀dà-ọ̀rọ̀. Àkíyési fihàn pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà ninú àkànlò èdè, àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti ẹ̀dà-ọ̀rọ̀ ni pọ́n-na ti ń jẹ jáde jù nínú ewi Yorùbá.  Ní ìkádìí, a ṣe àkíyèsí pé pọ́n-na bù ẹwà kún ewì, o sì dàbí bí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran jọ̀bọ̀jọ̀bọ̀ tó mú kí ewì dùn.

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

Pọ́n-na: Àtiwáyé Àti Ìṣẹ̀dá Rẹ̀ Nínú Ewì Yorùbá. (2026). Láàńgbàsà, 25(1), 36-49. https://doi.org/10.5281/zenodo.20757721