ÌLỌSÍWÁJÚ ÈDÈ YORÙBÁ ÀTI IPA TÍ ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ Ń KÓ LÓRÍ RẸ̀

Authors

  • Ọládiípọ̀ AJIBÓYÈ Yunifásítì ti Èkó Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20757966

Abstract

Àpilẹ̀kọ yìí ṣe àyẹ̀wò ìlọsíwájú tó ti dé bá èdè Yorùbá àti ipa tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ń kó lórí ìdàgbàsókè rẹ̀ lóde òní. Èdè tó bá ti di kíkọ sílẹ̀ tí a sì ń lò láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ti di gbájúgbajà èdè. Ẹ̀rí tó dájú wà wí pé Yorùbá ti wà lákọsílẹ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́, a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé ní gbogbo ìpele ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún gbọọrọ. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, láti mú kí ó rọ́rùn ní kíkọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ, akitiyan díẹ̀ ni ìjọba, àwọn olórí ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn olùkọ́ sà láti pèsè àwọn èròjà ìkọ́ni tó yẹ ní lílò. Ṣùgbọ́n lóde òní, àwọn èròjà ọjọ́un wọ̀nyẹn, bí wọ́n tún ti kéré tó, wọn kò wúlò mọ́. Bí ayé bá yí, ṣe ló yẹ̀ ká báyé yí. Ohun tí àpilẹ̀kọ yìí dojúkọ ni èdè Yorùbá àti àmúgbòòrò rẹ̀ pàápàá lórí abala tó jẹ mọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Mo wo ìṣàmúlò oríṣiríṣi ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìṣàmúlò ìtàkùn àgbáyé láwùjọ Yorùbá àti bí wọ́n ṣe ń mú ìtẹ̀síwájú bá èdè náà. Lára àwọn ohun ti mo gbé ṣe nínú pépà náà ni àmúgbòòrò kíkẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá. Mo ṣàfihàn rẹ̀ pé yàtọ̀ sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn ìtàkun ayélujára tàwọn lájọlájọ àti tàdáni ló ti wà ní àrọ́wọ́tó tí wọ́n sì ti ń kọ́ ẹ̀lẹ́kajẹ̀ka ẹ̀kọ́ Yorùbá. Mo tún ṣe àfihàn àti àlàyé rẹ̀ pé oríṣiríṣi àmúlò àwọn ẹ̀rọ bí èyí tó ń ṣògbufọ̀ sí èdè Yorùbá, ẹ̀rọ ìwé atúmọ̀ èdè Yorùbá, áàpù tó ń kọ́ni ní èdè Yorùbá b.a. mesmerise, duolingo, Yoruba101 abbl. ni ó ti wà ní àrọ́wọ́tó olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà ni mo sọ nípa ìwúlò àti ìtẹ̀síwájú tí àwọn ìkànni ìkọ́ni àti èròjà aápù ti mú bá ẹ̀kọ́ Yorùbá àti ìdàgbàsókè rẹ. Mo wá tẹ̀síwájú láti wo ọṣẹ́ tí àmúlò àwọn ẹ̀rọ àti oríṣiríṣi áàpù ń ṣe èdè náà. Ní ìgúnlẹ̀, mo pàrọwà sí ìjọba, àwọn lájọlájọ, àti àwọn ilé ìwé, bóyá ti ìjọba àbi àdáni láti ṣe àtìlẹyìn tó tó fún ìpèsè àwọn èròjà ẹ̀kọ́ túntun wọ̀nyí ní ilé ìwé gbogbo láti mú kíkọ́ ẹ̀kọ́ Yorùbá túbọ̀ rọrùn, kó sì gbòòrò si, kí àwa tí a jẹ́ olùkọ́ má sun àsùnpiyè lórí ohun tó ń lọ lórí ìkànnì ayélujára lórí bí kíkọ́ àti kíkọ èdè Yorùbá fi di irú wá, ògìrì wá.

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÌLỌSÍWÁJÚ ÈDÈ YORÙBÁ ÀTI IPA TÍ ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ Ń KÓ LÓRÍ RẸ̀. (2026). Láàńgbàsà, 25(1), 50-57. https://doi.org/10.5281/zenodo.20757966