O̩GBÓ̩N ÌS̩ÈWÁDÌÍ NÍNÚ LÍTÍRÉS̩Ò̩ ÀTI ÈDÈ YORÙBÁ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20758236Keywords:
Èdè Yorùbá, lítírés̩ò̩ Yorùbá, o̩gbó̩n ìs̩è̩wádìí, ìko̩sílè̩ fún ìrántí, ìfìwádìí-so̩tumò̩Abstract
Ìwádìí kó ipa pàtàkì nínú ìdáàbòbò àti ìtànkálè̩ èdè àti lítírés̩ò̩ Yorùbá, kí ìlo̩síwájú le è bá ìmò̩ è̩dá-èdè àti às̩à Yorùbá. Odù tí kì í ṣe àìmọ̀ olóko ni ìwádìí jẹ́ láwùjọ Yorùbá. Kí ìmọ̀ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà tó ó de ni àwọn baba ńlá wa ti ń ṣe ìwádìí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí àwọn baba ńlá wa tó dáwọ́lé ohunkóhun, wọ́n á kọ́kọ́ bi ifá léèrè. Ìwádìí yìí ló ṣe okùnfà onírúurú ètò àwùjọ, ètò ọrọ̀-ajé, òfin, èèwọ̀, ìlera, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àti èro báyéṣerí àwọn baba ńlá wa. Àkíyèsí tí a s̩e ni pé ìs̩òrò ńlá ni fún ò̩pò̩ àwo̩n aké̩kò̩ó̩ láti s̩àkójo̩ ohun èlò fún àyè̩wò, àti ìjábò̩ ìwádìí tí wó̩n s̩e. Pépà yìí s̩e àgbéyè̩wò ò̩nà tí àwo̩n aké̩kò̩ó̩ lè gbà s̩e ìwádìí nípa s̩ís̩e àmúlò o̩gbó̩n ìwádìí àti jíjábò̩ ìwádìí nínú è̩kó̩ èdè, às̩à àti lítírés̩ò̩ Yorùbá lóde-òní. Nípa s̩ís̩e àmúlò àwo̩n ohun àkójo̩ fún àyè̩wò nínú ìmò̩ è̩dá-èdè, lítírés̩ò̩ àti às̩à, pépà yìí wo àwo̩n ò̩nà tí a lè gbà s̩e àtúpalè̩ ohun àkójo̩ fún fáyèwò èdè, ewì, òwe, eré-onís̩e, ìtàn -àròso̩ àti ìs̩èré. Is̩é̩ yìí wo àwo̩n ìs̩esí o̩mólúàbí lóko ìwádìí, s̩ís̩e àdàko̩ àti ìdàko̩ àwo̩n ohun àkó̩jo̩ fáye̩wò lókò ìwádìí àti ìlànà tí a fi lè dáàbòbò àwo̩n ohun àkójo̩ fún àyè̩wò. Pépà yìí tó̩ àwo̩n aké̩kò̩ó̩ àti as̩èwádìí só̩nà lórí àtimo̩ àwo̩n kókó pátákí nínú ìwádìí, bí i; yíyan orí-ò̩rò̩ ìwádìí, ibi ìwádìí doríkó̩, aáyan ìwádìí, àti o̩gbó̩n ìs̩èwádìí.
