ÌFÌWÁDÌÍ-SỌ̀TUMỌ̀ ÀWỌN ÌYÁNRỌ̀FẸ́Ẹ́RẸ́ INÚ ORÍKI ỌBA LÁDÌGBÒLÙ KÌNNÍ ÀTI ADÉYẸMÍ KẸTA
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20758464Keywords:
Aláàfín, ìfìwádìí-sòtumọ̀, Ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́, Oríkì, Ọ̀yọ́Abstract
Bí a bá ta á, à á tọ̀ ọ́ ni, kó má baà dẹran onídin. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ti lọ lórí ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́ nínú lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá ṣùgbọ́n, àkíyèsí wa ni pé, kò tí ì sí ẹni tó ṣiṣẹ́ lórí ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́ nínú àwọn oríkì Aláàfin Ọ̀yọ́. Ìyánrọ̀fẹ́ẹ́rẹ́ sì ni àwọ́n ọ̀nà tí à á fi í pàṣamọ̀ ọ̀rọ̀ nínú afọ̀ láì tú iṣu dé ìsàlẹ̀ kòkò tí kò sì ní pa ìtumọ̀ afọ̀ lára. Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé ló kórajọ di oríkì tí ó sì jẹ́ pé gbólóhùn àti ọ̀rọ̀ pọ̀ níbẹ̀ tí wọ́n lóyún ìtumọ̀ sínú. Èròńgbà iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti le tọpinpin àwọn ìtàn tí ó rọ̀ mọ́ oríkì Aláàfin Ládìgbòlù kìíní àti Aláàfin Adeyẹmi kẹta torí pé àwọn méjèèjì ni wọ́n pẹ́ jù lórí àpèrè babaa wọn nínú àwọn Aláàfin mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí wọ́n ti jẹ ní Ọ̀yọ́ ìsìnyí láàrin ọdún 1835 sí 2022. Isẹ́ yìí tọpinpin àwọn ìtumọ̀ yìí nípa ṣíṣe àmúlò tíọ́rì ìfìwádìí-sòtumọ̀ (Hermaneutics). Ọgbọ́n ìsọ̀tàn O-ṣojúù-mi-kòró ni a gbà fi gbé iṣẹ́ náà kálẹ̀ gẹ́gé bí akópa nínú oríki Aláàfin Ọ̀yọ́. Iṣẹ́ yìí fi múlẹ̀ pé, ọ̀pọ̀ ìtàn ló kẹnú sínú oríkì àwọn Aláàfin tí ó sì yẹ kí á ṣàlàyé rẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Yorùbá.
