ÌJỌBA Ọ̀DẸ̀DẸ̀: ÌGBÉLÉWỌ̀N IPA OBÌNRIN NÍNÚ ÈTÒ-ÌṢÈLÚ INÚ ẸBÍ NÍNÚ ÀṢÀYÀN ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN YORÙBÁ

Authors

  • Olufadekemi ADAGBADA Department of Linguistics and Nigerian Languages Olabisi Onabanjo University, Ago-Iwoye Author
  • Edinrin Olúwatóyìn BỌ́LÁRÌNWÁ Department of Yoruba, Federal College of Education (Special), Oyo Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20766678

Keywords:

Eré-Onítàn Yorùbá, Ètò-ìṣèlú, Ìjọba Ọ̀dẹ̀dẹ̀, Obìnrin

Abstract

Inú ẹbí ni orírun ètò-ìṣèlú Yorùbá, ibẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ nínú ojúṣe àti ipa obìnrin fìdí kalẹ̀ sí. Ipa àti ipò àwọn obìnrin nínú ètò-ìṣèlú inú ẹbí fi hàn pé lọ́wọ́ àwọn obìnrin ni àṣẹ ilé wà, ibi tí ó bá sì wù wọ́n ni wọ́n lè darí ọkùnrin sí nínú ilé. Àfojúsùn iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò àti ìtúpalẹ̀ ipa àwọn obìnrin nínú ètò-ìṣèlú abẹ́lé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń jẹ yọ nínú àwọn àṣàyàn ìwé eré-onítàn Yorùbá. Iṣẹ́ yìí wo ipa àwọn obìnrin tí ó wà ní abẹ ọ̀dẹ̀dẹ̀ ọkọ àti àwọn obìnrin tí wọn kò sí ní abẹ́ àṣẹ ọkùnrin. Àwọn ìwé eré-onítàn Yorùbá tí a ṣà yàn jẹ́ méje, àwọn ìwé náà sì ni Baṣọ̀run Gáà, Ààrẹ Àgò Àríkúyẹrí, Gbònǹkáà Ẹkùn Abìjàwàrà. Etíògbejì, Ògún Lákáayé, Olú Ọmọ àti Ẹfúnṣetán Aníwúrà. A ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí ní ìlànà tíọ́rì Ṣoṣiọ́lọ́jì lítíréṣọ̀. Iṣẹ́ yìí fi hàn pé agbára obìnrin nínú ètò-ìṣèlú inú ìdílé fì sí ọ̀d̀ọ̀ àwọn obìnrin ju àwọn ọkùnrin lọ. iṣẹ́ yìí fi hàn pé àwọn obìnrin ni ó ń mú ilé rọrùn fún àwọn ọkùnrin, àwọn sì ni gbẹ́bíró nínú ètò-ìṣèlú abẹ́lé. Iṣẹ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn obìnrin tó olórí-ẹbí ṣe, wọ́n ní agbára láti kọ ìyà, àwọn obìnrin náà ni ó sì ń darí ètò ọpọ ẹbí ní abẹ́lé.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÌJỌBA Ọ̀DẸ̀DẸ̀: ÌGBÉLÉWỌ̀N IPA OBÌNRIN NÍNÚ ÈTÒ-ÌṢÈLÚ INÚ ẸBÍ NÍNÚ ÀṢÀYÀN ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN YORÙBÁ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 9-18. https://doi.org/10.5281/zenodo.20766678