ÀJÙLỌ ÀTI ÌJÁKULẸ̀ Ẹ̀DÁ-ÌTÀN NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÌWÉ ÌTÀN ÀRÒSỌ YORÙBÁ

Authors

  • Paul Akíntúndé AKÍNWÙMÍ Department of Linguistics and African Languages Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Osun State. Author
  • Adéwálé Lukman ADEMUYIWA Department of Linguistics and African Languages Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Osun State. Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20766884

Keywords:

Àjùlọ, Ẹ̀dá-Ìtàn, Ìjákulẹ̀, Ìtàn Àròsọ Yorùbá

Abstract

Ọ̀kan pàtàkì nínú ọ̀nà láti mọ ìhà tí ọ̀ǹkọ̀wé kọ sí ìwé lítíréṣọ̀ tí ó kọ àti ìhà tí ọ̀ǹkàwé kọ sí ìwé lítíréṣọ̀ tí ó kà ni àgbéyẹ̀wò àwọn ipa àti ipò ẹ̀dá-ìtàn tí òǹkọ̀wé lò nínú iṣẹ́-ọnà ajẹmọ́-lítíréṣọ̀ alátinúdá rẹ̀. Ìdí ni pé wíwo èyí máa ń ṣe àfihàn ojú ìwòye òǹkọ̀wé àti òǹkàwé nípa ìtàn inú lítíréṣọ̀. Ìlépa iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣọ̀rí àwọn ẹ̀dá-ìtàn méjì nínú àwọn àṣàyàn ìwé ìtàn àròsọ Yorùbá. Àwọn òǹkọ̀wé ìtàn àròsọ̀ tí a yẹ ìwé wọn wò jẹ́ mọ́kànlá, nígbà tí àwọn ìwé ìtàn àròsọ tí a tọ́ka sí jẹ́ méjìdínlógún, àwọn òǹkọ̀wé náà àti àwọn ìwé ìtàn àròsọ wọn ni I.B Thomas (Ìtàn Èmi Ṣẹ̀gilọlá Ẹlẹ́yinjú Ẹgẹ́ Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọkọ Láyé), D.O Fágúnwà (Ògbójú Ọdẹ nínú Igbo Irúnmọlẹ̀, Igbó Olódùmarè), Akíntúndé Ṣówùnnmí (Àyọ̀ká Fẹ̀láyọ̀), Ògúnsínà Ògúndélé (Ibú Olókun), Ọládẹ̀jọ Òkédìji (Àjà Ló Lẹrù, Àgbàlagbà Akàn, àti Ká rìn, Ká Pọ̀, Atótó Arére), Kọ́lá Akínlàdé (Owó Ẹ̀jẹ̀, Ọwọ́ Tẹ Amòòkùnsìkà, Àsírí Amòòkùnjalè Tú, Amọniṣeni), Adébáyọ̀ Falétí (Ọmọ Olókùn Ẹsin), Ọlátúnjí Ọ̀pádọ̀tun (Aápọn Pin),  Débọ̀ Awẹ́ (Jìjì Arẹwà Obìnrin), Olúségun Fátùrótì (Lórí Òkè Saikọfìlọ́), Bísí Adéṣígbìn (Ọjọ́ Burúkú Èṣù Gbomi Mu). A ka àwọn àwọn ìwé ìtàn àròsọ wọ̀nyí a sì ṣe àfàyọ àwọn kókó-èrò tí ó jẹ mọ́ àbùdá àwọn àṣàyàn ẹ̀dá-ìtàn inú wọn. Tíọ́rì àmúlò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí ni tíọ́rì Sosíọ́lọ́jì Lítíréṣọ̀ àti tíọ́rì Máàsì. Ìṣọ̀rí àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí a tọ́ka sí ni àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí ó tayọ àti àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n rí ìjákulẹ̀. Iṣẹ́ yìí ṣe àfìhàn àbùdá tí ẹ̀dá-ìtàn kan lè ni tí ó fi lè jẹ́ ẹ̀dá-ìtàn tí ó tayọ nínú ìtàn àti àbùdá tí ẹ̀dá-ìtàn kan lè ni tí a fì lè sọ pé ó tọ láti káàánú rẹ̀ nípa ìjákulẹ̀ rẹ̀ nínú ìtàn. 

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÀJÙLỌ ÀTI ÌJÁKULẸ̀ Ẹ̀DÁ-ÌTÀN NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÌWÉ ÌTÀN ÀRÒSỌ YORÙBÁ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 19-31. https://doi.org/10.5281/zenodo.20766884