ÀGBÉYẸ̀WÒ ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN ÀLÁ NÍNÚ ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN ÀWÒDÌ ÒKÈ TÍ ỌLÁTÚNDÉ LÁWUYÌ-ÒGÚNNÍRAN KỌ

Authors

  • Wahab Táíwò BÁKÀRÈ Department of Languages, Local Authority Commercial Grammar School, Ìwó, Ọ̀ṣun State Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20767014

Keywords:

Àlá, Aṣolobó, Eré-onítàn, Ìwà Ìbàjẹ́, Àwùjọ, Ọgbọ́n-Ìsọ̀tàn

Abstract

Ọ̀kan lára lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ tí òǹkọ̀wé oníṣẹ́-ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ máa ń gbé kalẹ̀ ní ìlànà ìsọ̀rọ̀-ǹ-gbèsì ni eré-onítàn jẹ́. Eré-onítàn yìí ni ìwé kíkọ alátinúdá tí òǹkọ̀wé ti máa ń sọ odidi ìtàn tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú èyí tó kéré tán àwọn ènìyàn bíi márùn-ún sí mẹ́wàá ti máa ń ṣe ìtàkurọ̀sọ tàbí nínú èyí tí àwọn ènìyàn bí ogún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ti máa ṣe ìjíròrò. Adébọ̀wálé (1999) àti Ọ̀pádọ̀tun (2004) ti sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ọ̀kan pàtàkì lára òǹkọ̀wé alátinúdá ni Ọlátúndé Láwuyì-Ògúnníran jẹ́, èyí ló mú ká yan ọ̀kan lára àwọn ìwé rẹ̀, láti ṣàgbéyẹ̀wò kókó iṣẹ́ ìwádìí wa yìí. Àfojúsùn iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wọ̀ ọgbọ́n ìsọ̀tàn àlá nínú ìwé eré-onítàn “Àwòdì Òkè” tí Ọlátúndé Láwuyì-Ògúnníran kọ. Ọgbọ́n-ìsọ̀tàn àlá ni a lò nínú pépà yìí, láti lè tú àṣírí àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí òǹkọ̀wé ṣàlàyé nínú ìwé eré-onítàn yìí, ká sì lè rí olobó ṣe fún àwọn ènìyàn àwùjọ. Pépà yìí ṣàlàyé nípa àwọn ìwà ìbàjẹ́ tó kún ọwọ́ àwọn ènìyàn àwùjọ pàápàá jùlọ àwọn aláṣẹ nínú ìlú. Pépà yìí fi yéni pé ọgbọ́n-ìsọ̀tàn àlá nìkan ni ó lè ṣolobó àwọn ìwà àwùjọ tó farasin.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÀGBÉYẸ̀WÒ ỌGBỌ́N ÌSỌ̀TÀN ÀLÁ NÍNÚ ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN ÀWÒDÌ ÒKÈ TÍ ỌLÁTÚNDÉ LÁWUYÌ-ÒGÚNNÍRAN KỌ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 32-40. https://doi.org/10.5281/zenodo.20767014