ÌFOJÚ ÀṢÀ ÀWÙJỌ ṢÀTÚPALẸ̀ ẸDAN NÍNÚ AWO ÒGBÓNI ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20767252Keywords:
Ẹdan, Èlè, Idẹ, Irin, ÒgbóniAbstract
Awo Ògbóni jẹ́ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀-ajẹmọ́ṣẹ̀ṣe àti àṣà Yorùbá. Ẹdan sì ni àmì ìmùlẹ̀ ẹgbẹ́ náà àti imọlẹ̀ tí wọ́n ń bọ. Ṣíṣe àtúpalẹ̀ Ẹdan Ògbóni ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwùjọ Yorùbá ni kókó àpilẹ̀kọ yìí. Iṣẹ́ yìí mú àtúpalẹ̀ Ẹdan Ògbóni ní ọ̀kúnkúndùn kí àwọn tí wọn kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ Ògbóni lè ní òye lórí bí Ẹdan ti ṣe pàtàkì tó àti ìwúlò rẹ̀ nínú awo Ògbóni àti ní àwùjọ Yorùbá lápapọ̀. Tíọ́rì Ìfàmìparokò (Semiotics) ni a fi ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí. Tíọ́rì Ìfàmìparokò jẹ́ ìlànà ìbánisọ̀rọ̀ láì ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ ẹnu. Àmì lílò pọ́ń-ń-bélé gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀ràn ilẹ̀ Amẹ́ríkà C. S. Pierce ti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ni a mú lò nínú iṣẹ́ yìí. Ọ̀nà tí a gbà ṣe àkójọpọ̀ détà ni ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lọ́dọ̀ àwọn àbẹ́nà ìmọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ògbóni. Bákan náà ni a ṣe àmúlò àwọn ìwé àti jọ́nà tí wọ́n wà ní àrọ́wọ́tó wa. Akáse, a tún ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayélujára. Àbájáde iṣẹ́ yìí ṣàfihàn Ẹdan Ògbóni gẹ́gẹ́ bí abiyamọ tí ó múlele nípa kí àwùjọ ọmọnìyàn ó lè máa dẹ tàbí búrẹ́kẹ nítorí kí ó má ba à parun. Iṣẹ́ yìí tún ṣe àfihàn idẹ àti èlè gẹ́gẹ́ bí irin tí wọ́n fi ṣẹ̀dá Ẹdan Ògbóni.
