OJÚ ÀMÚWAYÉ YORÙBÁ NÍNÚ ÌPOHÙN ỌDÚN ỌBA-Ò-DỌRỌ̀ NÍ ÌLÚ TEDÉ

Authors

  • Rashidat Adeseun OGUNDEJI Department of Yoruba, Federal College of Education, Iwo Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20767376

Keywords:

Ìpohùn, Ọba-ò-dọrọ̀, Ọdún ìbílẹ̀, Ojú Àmúwayé, Tedé

Abstract

Ìlepá iṣẹ́ ìwádìí yìí ni láti ṣe àfihàn ojú àmúwayé nínú ọdún Ọba-ò-dọrọ̀, èyí tí ó jẹ́ ọdún ìbílẹ̀ pàtàkì tí wọ́n ń ṣe ní ìlú Tedé ní agbègbè Òkè-Ògùn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò iṣẹ́ ìwádìí yìí wáyé nípa ṣíṣe àkójọ àwọn afọ̀ ajẹmọ́-ìpohùn tí wọn ń lò níbi ọdún ìbílẹ̀ yìí. Ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí gbára lé ìlànà tíọ́rì Ìfìwádìí-sọ̀tumọ̀, èyí tí ó jẹ́ tíọ́rì tí ó wúlò fún ìtúpalẹ̀ àwọn lítíréṣọ̀ ajẹmẹ́sìn àti ajẹmáṣà. Ojú àmúwayé Yorùbá tí iṣẹ́ yìí ṣe àfihàn jẹ́ kókó-èrò mẹ́ta. Àwọn sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn aláṣekù, èrò nípa iṣẹ́ ṣíṣe àti ìgbàgbọ́ nínú ìwúre. Ìgbàgbọ́ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àwọn ìgbàgbọ́ tí ó ti di ohun àtirandéran ní ìlú Tedé, wọn sì jẹ́ àwọn ìlànà tí ó jẹ́ àtọná fún ètò-ìgbé ayé àwọn ènìyàn ìlú náà.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

OJÚ ÀMÚWAYÉ YORÙBÁ NÍNÚ ÌPOHÙN ỌDÚN ỌBA-Ò-DỌRỌ̀ NÍ ÌLÚ TEDÉ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 56-62. https://doi.org/10.5281/zenodo.20767376