ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀ YORÙBÁ NÍPA OBÌ DÍDÀ GẸ́GẸ́ BÍ ÌLÀNÀ YẸ̀MÍWÒ

Authors

  • Omowunmi Ajoke MORDI Federal College of Education, Abẹ́òkúta Author
  • Olawoye Ifaleke AMOSUN Federal College of Education, Abẹ́òkúta Author
  • Oluwakemi Modupe OLUWO Federal College of Education, Abẹ́òkúta Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20767464

Keywords:

Àwọn Àwòrò Awo, Àwùjọ Yorùbá, Ìgbàgbọ́ Yorùbá, Obì dídà, Yẹ̀míwò

Abstract

Igba ọ̀nà ló wọlé àwúrèbe ni ìlànà Yẹ̀míwò nílẹ̀ Yorùbá. Yẹ̀míwò lè jẹ́ nípa Ifá dídà (Ikin àti ẹẹ́rìndínlógún), Agbigba, Omiwíwò, Èèpẹ̀ títẹ̀ àti Obì dídà. Láti ayébáyé ni àwọnYorùbá tini ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣeìwádìí lórí ohun tí ó bá rú wọn lójú tàbí tí wọ́n bá fẹ́ mọ ìdí àbájọ ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Bèèrè bèèrè kì í ṣì béèrè, èyí lò ń fà á jùlọ tí Yorùbá fi ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ nínú Yẹ̀míwò. Pépà yìí tọpinpin àwọn ọ̀nà tí àwọnYorùbá ń gbà ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìíìpín lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́ pẹ̀lú ìrètí pé ìdààmú àtì ìṣòrò ayé wọn yóò dópin ní kété tí wọ́n bá ti lọ fún yẹ̀míwò. Bákan náà, Pépà yìí ṣàfihàn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ lórí Obì dídà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìbánisọ̀rọ̀ láàrínàwọnimọlẹ̀ àtiòrìṣà. Pépà yìí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé obì dídà jẹ́ ọ̀nà tí àwọnYorùbá ń gbà bá àwọnIrúnmọlẹ̀ wọn sọ̀rọ̀,bẹ́ẹ̀ ní kò sí ẹnití ó mọ èdè Àyàn bí ẹnití ó mú Kọ̀ǹgọ́ rẹ̀ lọ́wọ́.Àwọnti ó wà ní ìdí òrìṣà wọ̀nyí ni ó mọ ohuntí obì ń sọ nigbà tí wọ́n bá da obì sílẹ̀. Ìlànà Dátà fún pépà yìí niìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lọ́dọ̀ àwọn Babaláwoàti àwọn Abọrẹ̀ Òrìṣà má́rùnún.  Tíọ́rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wo tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn àwùjọ àti ìgbàgbọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní tíọ́rì àmúlò fún àlàyé tí ó múnà dóko fún pépà yìí.Ipa ìbọ ni obì dídà wà fún, pépà yìí yóò jẹ́ kí á mọ ipa obì nínú ìlànà ìwádìí nílẹ̀ Yorùbá àti bí àwọn Babańlá waṣe ń túmọ̀ obì tí wọ́n bá dà pẹ̀lú tí túmọ̀ ohuntí obì bá sọ fún ẹni tí wọ́n torí rẹ̀ dabì. Pépà yìí yóò jẹ́ kí a ní ìmọ̀ kíkún nípa ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, èrò wọn, ojú àmúwayé wọn, àṣà àti ìṣesí wọn nípa fifi obì dídà ṣe yẹ̀ńwò.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀ YORÙBÁ NÍPA OBÌ DÍDÀ GẸ́GẸ́ BÍ ÌLÀNÀ YẸ̀MÍWÒ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 63-73. https://doi.org/10.5281/zenodo.20767464