SÍŃTÁÀSÌ ÌPÈDÈ ÌJERÒ ÀTI MỌ̀BÀ: ÌJÁBỌ̀ ALÁBỌ́DÉ

Authors

  • Oluyomi Christiana KEKERE-ODE Department of Linguistics, African and Asian Studies University of Lagos Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20767567

Keywords:

àgbéyẹwò, àpólà, ìbéèrè, ìpèdè, síńtáàsì

Abstract

Ọ̀nà ìbéèré àti ìtẹnumọ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ gírámà-onidàrọ́ olófin méjì tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú Yorùbá àjùmọ̀lò èyí tí a ti ṣàlàyé nínú ìwádìí yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ aṣewádìí, ìwọ̀nba díẹ̀ ni a mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí ní ìpèdè Ìjerò àti Mọ̀bà àwọn ìpèdè méjì tí ó wà ní àárín gbùngbùn Yorùbá. Ìwádìí yìi ṣe àyẹ̀wo ìpìlẹ̀ ọ̀nà ìbéerè àti ìtẹnumọ̀ ní ìpèdè Ìjerò àti Mọ̀bà pẹ̀lú àfiwé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú èdè Yorùbá àjùmọ̀lò. Ìwádìí yìí ṣe àfihàn díẹ̀ nínú àwọn ìjọ̀ra àti ìyàtọ̀ tí ó wà láàárìn àwọn ẹ̀ka èdè méjèèjì. Bí ó ti rí ní Yorùbá àjùmọ̀lò, ọ̀rọ̀ ìbéèrè ní èdè Yorùbá ń wáyé lẹ́yìn wúnrẹ̀ tí à ń ṣe ìtẹnùmọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí nínú Yorùbá àjùmọ̀lò. Lákòòtán, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Yorùbá àjùmọ̀lò, ìbáṣepọ̀ wà láàárín síńtáàsì ọ̀nà ìbéèrè àti ìtẹnumọ̀ ní ìpèdè Ìjerò àti Mọ̀bà nítorí pé àwọn méjèèjì ni ó ń lo atọ́ka fún ìṣèbéèrè àti ìtẹnumọ́ wọn. Ìwádìí yìí jẹ́ kí a mọ bí àwọn ẹ̀ka ède méjèèjì yìí ṣe ń ṣe ìbéèrè àti ìtenumọ́ wọn.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

SÍŃTÁÀSÌ ÌPÈDÈ ÌJERÒ ÀTI MỌ̀BÀ: ÌJÁBỌ̀ ALÁBỌ́DÉ. (2026). Láàńgbàsà, 24(1), 74-80. https://doi.org/10.5281/zenodo.20767567