OJÚÌWÒYE NÍPA ÌTÀN ÌṢẸ̀ǸBÁYÉ LÓRÍ PÀTÀKÌ ÌLERA, ÀÌSÀN, ÌTỌ́JÚ ÀTI ÌWÒSÀN Ẹ̀DÁ LÁTI INÚ ẸSẸ IFÁ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20767614Keywords:
Àìsàn, Ìlera, Ìwòsàn, Ojúìwòye Ifá, YorùbáAbstract
Pépà yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ojuàmúwayé Ifá àti àwọn ìtàn tó rọ̀ mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ Ifá tí a lò ní ìbámu pẹ̀lú kókó-ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìlera pípé fún ẹ̀dá. Ọ̀rọ̀ tí Yorùbá ń pè ní, ìlera, àìsàn, ìtọ́jú, ìwòsàn, jùmọ̀ máa ń kọ́wọ̀ọ́rìn nípa ìlera ẹ̀dá wà ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan ni. Àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ajẹmáṣà-ẹ̀dá yìí jẹ jáde nínú ìgbé-ayé ẹ̀dá àti ohun tó rọ̀ mọ́ lílépa àfojúsùn ènìyàn kọ̀ọ̀kan láwùjọ. Ọ̀rọ̀ tí Yorùbá ń pè ní ìlera ẹ̀dá ṣe pàtàkì ju ohunkóhun lọ ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá tàbí ohun tó lè fẹ́ lépa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó rọ̀ mọ́ lílépa àfojúsùn ènìyàn kọ̀ọ̀kan láwùjọ àti èròǹgbà ènìyàn kọ̀ọ̀kan ló yàtọ̀, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ìlera jẹ ìkóríta ti gbogbo ènìyàn kò le fojú rénà nínú akitiyan láti làlùyọ láyé. Èyí ló ṣàpèjúwe ìpele wíwàláyé, àti wíwàláàyè ènìyàn kọ̀ọ̀kan àti bí ènìyàn yó ti ní ìgbáyégbádùn tó. Àmọ́ ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ó túmọ̀ sí pé, ènìyàn lè wà láyé bí aláìsí bí ènìyàn bá dùbùlẹ́ àìsàn tàbí tí kò ní owó láti tọ́jú ara fún ìlera tó péye. Wíwo iṣẹ́ àwọn onímọ̀ tó wà nílẹ̀ tún fún wa ní àǹfàání láti mọ ibi tí iṣẹ́ akadá dé dúró nípa àkòrí ọ̀rọ̀ yìí láwùjọ Yorùbá. A ṣe òrínkínníwín àlàyé nípa àwọn àṣàyàn ẹsẹ Ifá mẹ́fà tí a lò bí àkójọ èdè fáyẹ̀wò wa. A ṣe àmúlò ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn Babaláwo méjì lórí kókó-ọ̀rọ̀ tí a gbéyẹ̀wò. Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti ni òye kíkún nípa ìtàn yẹ̀ńwò àti èrò-ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Ifá nípa ìlera. Àmúlò òwe, bí ìtọsẹ̀, ràn wá lọ́wọ́ láti gbe àlàyé wa lẹ́sẹ̀. Bákan náà, a tún fi ojú lámèetọ́ wo ìsọ̀rí àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tó jẹ mọ́ Ifá bí àfikún ìmọ̀. Àbọ̀ ìwádìí jẹ́ kí á mọ̀ pé, ìlànà ìwòsàn tó péye ń bẹ láwùọ Yorùbá ní ìbámu pẹ̀lu bí Ifá ti là á kalẹ̀ pẹ̀lú ìtàn-ìwáṣẹ̀ tó rọ̀ mọ́ ìlera ènìyàn. Bí Ifá ti jẹ́ Òpìtàn ilẹ̀ Ifẹ̀ ló sì tún rán wá létí pé, “ìlera loògùn ọrọ̀; fún gbogbo ẹ̀dá inú àwùjọ.”
