ÀKÓBÁ ÀÌSÀN AJẸMỌ́-ÒPÓNÀ-AJẸMÓHÙN ÀTI TOJÚ-TẸNU FÚN ÀBÙDÁ ÌṢAFỌ̀ LÁÀRIN ÀWỌN ỌMỌDÉ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20771972Keywords:
Òpónà-Ajẹmóhùn, àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn-àti-tojú-tẹnu, àìsàn ajẹmọ́-ìbímọ, ìlera ènìyàn, àjàkálẹ̀-àrùnAbstract
Ìwádìí fi hàn pé, àwọn iṣẹ́ ìwádìí tó wáyé ní Ẹ̀ka-ìmọ̀ ètò-ìlera ti pọ̀ lórí àwọn àìsàn tí ó jẹ mọ́ ìtọ́jú àwọn aboyún àti àwọn ọmọdé. Bákan náà ni ìwádìí ti wáyé lóríṣìíríṣìí nípa àwọn àìsàn-àjàkálẹ̀, àìsàn-ajẹmọ́-inú, àìsàn-ajẹmọ́pọlọ àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀. Kò dájú pé ìwádìí tó wáyé lórí àwọn àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn àti tojú-tẹnu ènìyàn pọ̀ tó ti àwọn ẹ̀yà àìsàn yòókù, pàápàá ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìwádìí yìí tẹpẹlẹ mọ́ àgbéjáde àwọn ìmọ̀ tó jẹ mọ́ okùnfà àti ìlànà ìṣèwòsàn fún àwọn àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn àti tojú-tẹnu. Olùwádìí ṣe àṣàyàn àwọn Dókítà àti àwọn aláìsàn tí irúfẹ́ àwọn àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn àti tojú-tẹnu yìí ń yọ lẹ́nu. Àwọn Ilé-ìwòsàn Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn mẹ́ta tó wà ní Ọ̀tà, Ìjẹ̀bú-Òde àti Abẹ́òkúta ni a yàn láàyò fún ìwádìí yìí. À ṣe ìfọ̀rọ̀-wáni lẹ́nu-wò fún àwọn Dókítà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn mẹ́jọ tí àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn-àti-tojú-tẹnu ń ṣe. A tún ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìpohùn tí àwọn Yorùbá ń lò gẹ́gẹ́ bí ohun-èlò fún ìtọ́jú àìsàn ajẹmọ́ òpónà-ajẹmóhùn àti tojú-tẹnu. Bákan náà ni a ṣe àmúlò àwọn ìwé àṣàyàn, jọ́nà ajẹmọ́-akadá, ìwádìí lórí ẹ̀rọ-ayélujára àti àwọn ìwádìí tó ti wáyé ṣaájú nípa ètò-ìlera. Àbàjáde ìwádìí yìí ni pé, àwọn ọmọdé ni àìsàn yìí sábà máa ń ṣe jù lọ. Ó túmọ̀ sí pé, kékeré ni àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn-àti tojú-tẹnu ti máa ń ṣe ènìyàn, ní èyí tí ó lè ṣe ọṣẹ́ fún òpónà-ajẹmóhùn àti àbùdá ìṣàfọ̀ fún èdè pípè. Àìsàn ajẹmọ́-òpónà-ajẹmóhùn àti tojú-tẹnu lè jẹ́ èyí tó jẹ mọ́ àìsàn-ìbímọ, àìtọ́jú-ọmọdé ní àkókò tí ó wà ní aròbó, àṣìlò oògùn àti àwọn àìsàn-ajẹmọ́-àyíká.Downloads
Download data is not yet available.
References
Downloads
Published
2025
Issue
Section
Articles
How to Cite
ÀKÓBÁ ÀÌSÀN AJẸMỌ́-ÒPÓNÀ-AJẸMÓHÙN ÀTI TOJÚ-TẸNU FÚN ÀBÙDÁ ÌṢAFỌ̀ LÁÀRIN ÀWỌN ỌMỌDÉ . (2023). Láàńgbàsà, 23(1), 11-24. https://doi.org/10.5281/zenodo.20771972
