ÀGBÉYE ̣̀WÒ KÓKÓ-O ̣̀RO ̣̀ NÍNÚ ORIN ÀYÌNLÁ ỌMỌWÚRÀ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20772104Keywords:
Orin ìbíle ̣̀, Àyìnlá Ọmọwúrà, Kókó o ̣̀ ro ̣̀, Ìwà ị̀bàje ̣́, Àtúnṣe àwùjọ,, Tị́o ̣́rị̀ ị̀bạ́ra-e ni-gbẹ́ po ̣̀ Wo Lị́tị́rẹ́s o ̣̀Abstract
O ̣̀po ̣̀ lọpo ̣̀ ènìyàn ni wọn kì í fi ara bale ̣̀ gbo ̣́ orin ìbíle ̣̀ ní àwùjọ wa mo ̣́ ; ijó tàka-súfèé ló kù táyé ń jó báyìí. Elẹ́yị̀ị́ ni ó túbo ̣̀ ń ṣokùǹfà bí o ̣̀po ̣̀ lọpo ̣̀ kókó àti e ̣̀ko ̣́ inú àwọn orin ìbíle ̣̀ Yorùbá kò ṣe lapa lára àwọn ènìyàn inú àwùjọ mo ̣́ lónìí. O ̣̀kan pàtàkì olórin ìbíle ̣̀ Yorùbá tí ó gbajúmo ̣̀ ni Àyìnlá Ọmọwúrà lára o ̣̀go ̣̀ ro ̣̀ olórin ìbíle ̣̀ láwùjọ Yorùbá. Bó ti le ̣̀ je ̣́ wí pé Àyìnlá Ọmọwúrà sábà máa ń dojú orin re ̣̀ kọ àwùjọ obìnrin lo ̣́po ̣̀ lọpo ̣̀ ìgbà, èyí kì í ṣe láti tàbùkù àwọn obìnrin, bí kì í ṣe láti pè fún ìṣàtúnṣe sí àwọn ìwà tí ó ń fe ̣́ àmójútó láàárin àwọn obìnrin láwùjọ. O ̣̀go ̣̀ ro ̣̀ obìnrin ni wo ̣́n sábà máa ń fi ojú ẹle ̣́e ̣̀ke ̣́-èébú wo o ̣̀kọrin yìí nípase ̣̀ ọ̣̀pọ̣̀lọpọ̣̀ àwọn orin tí a me ̣́nubà yìí, ṣùgbo ̣́n a ṣàkíyèsí wí pé èébú àti àyínsí inú àwọn orin wo ̣̀nyí nìkan ni o ̣̀po ̣̀ lọpo ̣̀ ń te ̣́ tí gbo ̣́ , wọn kò fi be ̣́e ̣̀ róye nípa àwọn kókó o ̣̀ ro ̣̀ mìíràn tí ó sodo sínú àwọn o ̣̀kan-ò-jo ̣̀kan orin o ̣̀kọrin náà. Yorùbá bo ̣̀ , wo ̣́n ní: “àìfe ̣̀ le ̣̀ ké ìbòsí ni àìfe ̣̀ le ̣̀ re ̣́ni jó o”. A wá lè sọ pé bóyá nítorí gbọnmọ gbọnmọ o ̣̀kọrin yìí tí ó po ̣̀ lápo ̣̀ jù lórí o ̣̀ ro ̣̀ obìnrin ni ó ń ṣokùǹfà àìróye àwọn kókó mìíràn tí ó farasin sínú orin re ̣̀ bí? Yorùbá sì tún bo ̣̀ , wo ̣́n ní: “bójú bá fara bale ̣̀ , á rímú”. Ohun tí iṣe ̣́ yìí tẹpẹlẹ mo ̣́ ni àgbéye ̣̀wò àwọn kókó o ̣̀ ro ̣̀ tí orin Àyìnlá Ọmọwúrà gùnlé pe ̣̀ lú àwọn e ̣̀ko ̣́ tí ó sodo sínú re ̣̀ láti fi ṣe àtúnṣe ìwà ìbàje ̣́ láwùjọ. Kókó o ̣̀ ro ̣̀ méje ni iṣe ̣́ yìí ye ̣̀wò nínú àwo re ̣́ko ̣́o ̣̀dù mo ̣́kànlá ṣáńgílítí lára ogún fo ̣́ lúùmù tí o ̣̀kọrin náà ṣe.Downloads
Download data is not yet available.
References
Downloads
Published
2025
Issue
Section
Articles
How to Cite
ÀGBÉYE ̣̀WÒ KÓKÓ-O ̣̀RO ̣̀ NÍNÚ ORIN ÀYÌNLÁ ỌMỌWÚRÀ . (2026). Láàńgbàsà, 23(1), 25-44. https://doi.org/10.5281/zenodo.20772104
