ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀṢÀYÀN IṢẸ́ ÀWỌN AKÉWÌ ÌṢÁÁJÚ, ÀTẸ̀LÉ ÀTI TI ÒDE-ÒNÍ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ỌMỌLÚÀBÍ FÚN ÌDÀGBÀSÓKÈ ÀWÙJỌ

Authors

  • Ejitoyosi Olayemi SALAMI Olabisi Onabanjo University, Ago-Iwoye Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20772872

Keywords:

Ìṣáájú, òde-òní, ewì, ìwà, ọmọlúàbí

Abstract

Láti ìbẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ ìgbésíayé ẹ̀dá, kò sí àsìkò kan tàbí ìgbà kan tí a kò rí àwọn ẹ̀dá tó ń hu ìwà kan tàbí òmíràn tí ó ta ko ìwà ọmọlúàbí. Àwọn ìwà wọnyí kàn ń yíra padà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gà lásán ni. Ṣàṣà akéwì ìṣáájú àti ti òde-òní ni kì í mẹnu ba ọ̀kan tàbí òmíràn àwọn ìwà tí ó dára àti ìwà àìdára inú àwùjọ nínú iṣẹ́ wọn. Iṣẹ́ yìí gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò àṣàyàn iṣẹ́ àwọn akéwì ìṣáájú, àtẹ̀lé àti ti òde-òní lórí ọ̀rọ̀ ọmọlúàbí àti àwọn ewì wọn tí ó tọ́ka sí ìwà tó bójúmu àti ìwà àìbójúmu. Àwọn tí a kà kún àwọn akéwì ìṣáájú ni àwọn tí iṣẹ́ wọn wà láàrin ọdún 1906 sí ọdún 1938. Àwọn tí a gbà gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀lé ni àwọn tí iṣẹ́ wọn wà láàrin ọdún 1939 sí 1973. A lo àwọn tí iṣẹ́ wọn wà láàrin ọdún 1975 títí di òní gẹ́gẹ́ bí akèwì òde-òní. A gbìyànjú láti tún mú àwọn akéwì ìṣáájú wọnyí wá sí ìrántí nítorí pé bí onírèsé wọn kò fíngbá mọ́, èyí tí wọn ti fín sílẹ̀ kò le parun. Nítorí náa, kò yẹ láti gbàgbé wọn. Àwọn akéwì ìṣáájú tí a lo iṣẹ́ wọn ni; Ṣówándé (1906) pẹ̀lú àtúnṣe ti Lijadu àti Babalọlá (1974), Bákan naa ni a lo isẹ́ Ajíṣafẹ́ (1921), A lo iṣẹ́ Ọdúnjọ (1949), Ọbasá (1971) àti Ọládàpọ̀ (1973) fún àtẹ̀lé nígbà tí a lo Ọládàpọ̀ (1975), Ọ̀pádọ̀tun (1976), (1987), (2005) àti Ológundúdú (2009) fún akéwì òde-òní. Tíọ́rì àṣà ni a lò fún iṣẹ́ yìí. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ipa ewì nínú àṣà àwùjọ kò kéré. Iṣẹ́ yìí ṣe àfiwéra sáà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ó tọ́ka sí àwọn ìwà tó dára tí a fi lè gbà ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlúàbí àti ìwà tí kò dára tí a fi le gba ènìyàn gẹ́gẹ́ bí aláìníwà ọmọlúàbí ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ wọn. Bákan náà, nínú ewì wọn, iṣẹ́ yìí ṣe àfihàn àtubọ̀tán àìníwà ọmọlúàbí ó sì ṣe àfihàn àwọn ìmọ̀ràn fún yíyàgò fún ìwà tí kì í ṣe ti ọmọlúàbí. Àrífàyọ iṣẹ́ yìí ni pé kò sí òdiwọ̀n kan pàtó tí ó fi ìyàtọ̀ nípa ohun tí Yorùbá kà sí ìwa ọmọlúàbí hàn láti ayé ìgbà àwọn akéwì ìṣáájú, àtẹ̀lé àti ti òde-òní. Isà kan náà ni ọdẹ wọn ń dẹ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé ọmọ tí ayé bí ni ayé ń pọ̀n. Iṣẹ́ yìí gba àwùjọ ní ìyànjú láti máa lèpa ìwà ọmọlúàbí ní ìgbà gbogbo. Ó tún gba àwùjọ níyànjú pé kí iṣẹ́ ìwádìí lórí ìwà ọmọlúàbí tẹ̀ síwájú láti túbọ̀ fọ àwùjọ mọ́.

 

Kókó Ọ̀rọ̀: Ìṣáájú, òde-òní, ewì, ìwà, ọmọlúàbí

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀṢÀYÀN IṢẸ́ ÀWỌN AKÉWÌ ÌṢÁÁJÚ, ÀTẸ̀LÉ ÀTI TI ÒDE-ÒNÍ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ỌMỌLÚÀBÍ FÚN ÌDÀGBÀSÓKÈ ÀWÙJỌ . (2026). Láàńgbàsà, 23(1), 45-59. https://doi.org/10.5281/zenodo.20772872