ÀS̩À ÀTI ÈDÈ O ̩GBÀ NÍNÚ ORIN WÀSÍÙ ÀLÀBÍ PÀSÚMÀ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20773003Abstract
Àjogúnbá ni orin jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì nínú ewì alohùn Yorùbá. Ọ̀nà kan pàtàkì tí àwọn Yorùbá máa ń gbà láti fi èrò ọkàn wọn hàn yálà ni ìgbà ìbànújẹ́ tàbí ayọ̀ ni orin sì tún jẹ́ pè̩lú. Pàtàkì iṣẹ́ ìwádìí yìí ní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àṣà àti èdè ò̩gbà nínú orin Wasiu Àlàbí Pàsúmà tí a mọ̀ sí fújì láti lè mọ àwo̩n ohun tí ó jé̩ àfojúsùn rè̩ gé̩gé̩́ bí òǹko̩rin. Tíọ́rì sosiọ́lọ́jì lítírés̩ò̩ ní a gùnlé láti s̩e àdàko̩ àti ìtúpalè̩ àwo̩n àwo orin Àlàbí Pàsúmà mé̩wàá. Lé̩yìn èyí ni a s̩e ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò pè̩lú òǹko̩rin náà, torí e̩ni mojú ògún níí pa obì nírè. Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé èdè ò̩gbà àti àṣà kún inú orin Pàsúmà fọ́fọ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ohun tí àwo̩n ọ̀dọ́ òde òní ń fé̩ ni ó ń dojú orin rè̩ ko̩. Bí ó ṣe ń fi orin rẹ̀ danílárayá bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń fi dánilẹ́kọ̀ọ́. Èyí ni orin rẹ̀ sì fi ń ṣe ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ.
