ÌFIWÉRA ÀṢÀ ÌSỌMỌLÓRÚKỌ LÁÀÁRÍN ÀWỌN YORÙBÁ ÀTI ÀWỌN ÒGÙ NÍ ÌLÚ ÀGBÁDÁRÌGÌ, NÍ ÌPÍNLE ̣̀ ÈKÓ

Authors

  • Títílayọ̣̀ Ọ̣̀NÁDÍPẸ̣̀-SHALOM Department of Linguistics, African Languages and Communication Arts, LASU, Ojo, Lagos. Author
  • Mercy NOVIYON Department of Linguistics, African Languages and Communication Arts, LASU, Ojo, Lagos. Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20773117

Keywords:

Àgbádárìgì, àṣà ìsọmọlórúkọ, Ògù, Yorùbá, ìtúpalẹ̀ aṣàfiwéra

Abstract

Pépà yìí dálé ìfiwéra àṣà ìsọmọlórúkọ láàárín àwọn Yorùbá àti àwọn Ògù ní ìlú Àgbádárìgì, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ìlú Àgbádárìgì jẹ́ àwùjọ elédè púpọ̀ tí àwọn Ògù àti àwọn Yorùbá ti ń bára wọn gbé láti ọjọ́ pípẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú ti tipa èyí di gbédègbẹ́yọ̀, Ìgbépapọ̀ yìí ti ṣe okùnfà ìwọnúra èdè àti àṣà Yorùbá àti Ògù.  Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìṣáájú tí ó ti wo àṣà ìsọmọlórúkọ àwọn Yorùbá kò ṣe àfiwéra àṣà ẹ̀yà méjéèjì. A ṣe iṣẹ́-ìwádìí yìí láti le mọ àwọn ìjọra àti ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹ̀yà méjèèjì yìí. Bákan náà, iṣẹ́ yìí yóò tànmọ́lẹ̀ sí ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ògù ṣe ń fún àwọn ọmọ wọn ní orúkọ Yorùbá gẹ́gẹ́ bi orúkọ àbísọ kìíní tàbí èkejì. Tíọ́rì Ìtúpalẹ̀ Aṣàfiwéra ni a lò fún iṣẹ́ yìí. Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpín-sí-sọ̀rí orúkọ Yorùbá bí i orúkọ àbísọ, àmútọ̀runwá, ìnagijẹ, orúkọ ìdílé àti iṣẹ́ ni ó farahàn nínú orúkọ Ògù. Bákàn náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ àkọ́kọ́ lè jẹ́ orúkọ Ògù / Kiristeni/Musulumi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn Ògù ni ó ní orúkọ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí orúkọ àbísọ kejì. Ìwádìí yìí fì̀dìí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀nà sọmọlórúkọ yìí fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́yà méji. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sísọ èdè Yorùbá wúlò, ti orúkọ́ Yorùbá mú èrè ńlá wá, síbẹ̀ pépà yìí mú un dání lójú pé àwọn Ògú fẹ́ràn àṣà wọn àti pé wọn kò fi orúkọ ìbílẹ̀ wọn ṣeré.

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÌFIWÉRA ÀṢÀ ÌSỌMỌLÓRÚKỌ LÁÀÁRÍN ÀWỌN YORÙBÁ ÀTI ÀWỌN ÒGÙ NÍ ÌLÚ ÀGBÁDÁRÌGÌ, NÍ ÌPÍNLE ̣̀ ÈKÓ. (2026). Láàńgbàsà, 23(1), 76-85. https://doi.org/10.5281/zenodo.20773117