ÌMÒ̩ O̩GBÓ̩N-ÀMÚS̩E ÀTI ÌDÀGBÀSÓKÈ ÀWÙJO̩ NÍNÚ EWÌ ALOHÙN YORÙBÁ: ÌGBÁLÁ SÍNSÍN GÉ̩GÉ̩ BÍ ÀPE̩E̩RE̩
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20775431Keywords:
ìmò̩ o̩gbó̩n-àmús̩e, ìmò̩ è̩ro̩, àwùjo̩, lítírés̩ò̩, ÌgbáláAbstract
Ò̩tun lo̩jó̩ ń yo̩ lò̩rò̩ ìmò̩. Ojú tí a gbà wo lítírés̩ò̩ alohùn nínú pépà yìí yàtò̩ sí is̩é̩ ti àwo̩n ará ìs̩áájú ti s̩e. Ohun tí ó kàn wá nínú is̩é̩ yìí ni àwo̩n kókó tí ó je̩ mó̩ ìmò̩ o̩gbó̩n-àmús̩e àti ìdàgbàsókè àwùjo̩ nínú lítírés̩ò̩ alohùn Yorùbá. Ò̩pò̩ ìs̩òrò ló ti s̩ú yo̩ láwùjo̩ o̩mo̩nìyàn látàre àìbìkítà àti àìko̩biara si ohun tí àwo̩n ará ìs̩áájú fi s̩e ìgbésí-ayé wo̩n. Èròǹgbà wa nínú is̩é̩ yìí láti wo ò̩nà tí àwo̩n apohùn gbà s̩e àmúlò àwo̩n is̩é̩ ìs̩è̩ǹbáyé Yorùbá nínú ewì alohùn àti bí wó̩n s̩e s̩àmúlò àwo̩n kókó tí ó lè mú ìdàgbàsókè bá àwùjo̩. A s̩e àkójo̩ èròjà àmúkalè̩ fáyè̩wò nípasè̩ ìs̩àkíyèsí òǹwòran àti ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò. Tíó̩rì ìmò̩ ìfìwádìí-sò̩tumò̩ ni a fi s̩e àtè̩gùn fún is̩é̩ yìí. Àbájádé is̩é̩ yìí fi hàn pé òye ńlá tí ó ga jù ni àwo̩n baba ńlá wa fi gbé àwo̩n is̩é̩ ìs̩è̩ǹbáyé wo̩n kalè̩ àtipé púpò̩ nínú àwo̩n ohun èlò àwùjo̩ náà ni ó s̩ì wúlò lóde òní. A wá dáa lábàá wí pe kí àwo̩n ará àwùjo̩ bè̩rè̩ sí ní s̩e àmúlò o̩gbó̩n tí àwo̩n ará ìs̩áájú lò láti s̩è̩dá àwo̩n ohun èlò wo̩n gbogbo nípa lílo ìmò̩ ìgbàlódé, èyí yóò mú ìlo̩síwájú bá ìmò̩ o̩gbó̩n-àmús̩e wa, yóò sì jé̩ kí ìdàgbàsókè bá àwùjo̩ wa.
