ÌTANIJÍ NÍPA Ọ̀RỌ̀ ÌṢÈLÚ NÍ ÌPELE ARA-ẸNI NÍNÚ ÀGBÉYẸ̀WÒ ÀṢÀYÀN ÀWỌN EWÌ ÀPILẸ̀KỌ (1999 – 2011)
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20775568Keywords:
Ìtanijí, ìjàgbara onípòjipò, Ìtakìjí, Ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú.Abstract
Iṣẹ́ ti pọ̀ jaburata lórí ọ̀rọ̀ Ìṣèlú pàápàá jùlọ láàrín àwọn ènìyàn ní orílèèdè Nàijíríà ṣùgbọ́n Ìtanijí lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kìí ṣe nípa òṣèlú ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ púpọ̀. Ìwòye iṣẹ́ yìí ni wí pé Ìṣèlú wà nínú ohun gbogbo tí a ń ṣe ní òde ìṣálayé. Òṣèlú wà nínú ètò ìgbéyàwó, ìsọmọlórúkọ, òkú ṣíṣe, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ọ̀rọ̀ ajé, ètò ìbára ẹni gbé pọ̀, ètò àwùjọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lááríjà tí a rí nínú iṣẹ́ yìí ni ìtọpinpin irúfẹ́ ìtanijí tí ó wà nínú ewì àpilẹ̀kọ nípa òṣèlú láti ọdún 2011. Tíọ́rì ìṣọwọ-lo-èdè Marxist ni òǹṣèwádìí yìí yàn láyò nítorí tíọ́rì yìí rí lítíréṣọ̀ bí ohun èlò ìjàjàgbara. Ìlànà ẹ̀kọ́ àti ìṣàpèjúwe lórí ewì ní òǹṣèwádìí lò gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ìṣèwádìí. Fún ìdí èyí, ọgbọ́n ìṣèwádìí ìmọ̀ ìtayọ nípa ohun tí a rí nì a ṣe àmúlò. Òǹṣèwádìí yìí fura wí pé ká ṣáà ní gbogbo rògbòdìyàn tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé, lẹ́nu iṣẹ àti ni orílẹ̀ èdè tí ó yan ìṣèjọba olówógbowó láyò ní ìmọ̀tara-ẹni-nìkan; rògbòdìyàn, kòṣeémanìí fún irúfẹ́ àwùjọ bẹ́ẹ̀ wà. Lára ohun tí ìwádìí yìí ṣe fún àwùjọ ìmọ̀ ní wí pé nípa ṣíṣe àfihàn irúfẹ́ ìtanijí tí àwọn akéwì tí a wo iṣẹ́ wọn nínú ìwádìí yìí, a ti ri dájú wí pé, àwọn òǹkọ̀wé ilẹ̀ Afíríkà mọ púpọ̀ nípa ètò ìṣèlú àti wí pé ìgbàgbọ́ wọn kún ojú òṣùwọ̀n láti yanjú gbogbo ìṣòro tí ó rọ̀ mọ́ ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣèlú àwùjọ ìgbàlódé ní ilẹ̀ Nàìjíríà
