ÀṢÀ ÌGBÉYÀWÓ YORÙBÁ GẸ́GẸ́ BÍ Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ SÍ ÌSÒRO ÌGBÉYÀWÓ TÍTÚKÁ LÁWÙJỌ ỌMỌNÌYÀN LÓDE ÒNÍ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20775844Keywords:
ìgbéyàwó, ìgbéyàwó títúká, àṣà ìgbéyàwó Yorùbá, ọ̀nà àbáyọ, àwùjọ, ọmọnìyànAbstract
Ọ̀rọ̀ ti pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀ ìgbéyàwó àti igbéyàwó títúká ní àwùjọ ọmọnìyàn lóde òní. Àmọ́, a kò tí rí akitiyan púpọ̀ lórí wíwá ìyanjú sí ìṣòro ìgbéyàwó títúká tí ó ń gbilẹ̀ láàárín ọmọnìyàn. Iṣẹ́ pàtàkì yìí ni pépà yìí fẹ́ jẹ́. Iṣẹ́ ìwádìí yìí gùnlé wíwo inú àṣà ìbílẹ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro àwùjọ, nítorí náà a ṣe àmúlò tíọ́rì ajẹmáṣà ìbílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn fún ìwádìí yìí. Pépà yìí wòye pé àwọn nǹkan pàtàkì tí wọ́n ń fa ìgbéyàwó títúká lóde òní bí àìrọ́mọbí, ẹ̀ṣìn, àtètègbéyàwó, àìlówó lọ́wọ́ àti àìní agbára láti pèsè fún ẹbí, àpadàsí-àìda tàbí ìyípòpadà, ipa àwọn ẹbí ọkọ àti ìyàwó, àìnítẹ́lọ́rùn àti ọ̀kánjúà, ìwà àgbèrè, àìlera àti ààrùn àti ìjà ojoojúmọ́ ni a lè dẹ́kun nípa ṣíṣe àmúlò àṣà ìgbéyàwó Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí a ń gbà ṣe ìgbéyàwó ní àwùjọ lóde òní. Pépà yìí ri dájú pé tí a bá tẹ̀lẹ́ àwọn ìgbéṣè àṣà ìgbéyàwó Yorùbá nínú àwọn ìgbéyàwó wa lónìí, a máa yanjú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ń fa ìgbéyàwó títúká èyí yóò sì jẹ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìsòro ìgbéyàwó títúká tí ó ń kojú àwon ìgbéyàwó yìí. Pépà yìí wòye pé fún ìlọsíwájú àwùjọ àti láti tán ìṣòro ìgbéyàwó títúká láwùjọ ọmọnìyàn lónìí, kí a padà sínú àṣà ìbílẹ̀ wa nípa ṣíṣe àmúlò àṣà ìgbéyàwó Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbéyàwó láwùjọ, kí eku lè ké bí eku, kí ẹyẹ lè ké bí ẹyẹ nínú àwọn ìgbéyàwó wa lóde òní nítorí bí a bá ṣe é bí wọ́n ṣe ń ṣe é, yóò rí bí ó ti yẹ kó rí.
