ÌṢÒRO ÌṢÀMÚLÒ Ẹ̀KA-ÈDÈ NÍNÚ EWÌ ÀPILẸ̀KỌ YORÙBÁ: EWÌ ṢÓBỌ̀WÁLÉ ṢÓWÁNDÉ BÍ ÀPẸẸRẸ

Authors

  • Ayọ̀délé Solomon OYÈWÁLÉ Department of Linguistics, African & Asian Studies University of Lagos, Àkọkà, Lagos. Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20775993

Keywords:

Yorùbá Àjùmọ̀lò, Ẹ̀ka-èdè Ẹ̀gbá, Ṣóbọ̀ Aróbíodu, Ìfèdèfọ̀, Ẹwà Èdè, Akéwì Ìgbàlódé

Abstract

Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àwọn òǹkọwé àti akéwì ìṣaájú ti fihàn, èdè Yorùbá àjùmọ̀lò ló gbajúgbajà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ akéwì Yorùbá fi máa ń kọ ewì wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Àmọ́, bí ọ̀wọ́ àwọn akéwì kan láti ilẹ̀ Ẹ̀gbá ti ṣe lo ẹ̀ka-èdè wọn ní ọ̀nà tó rẹwà fún kíkọ ewì pẹ̀lú ọgbọ́n àtinúṣẹ̀dá jẹ́ ohun ìwúrí tó yàtọ̀ nínú ewì àpilẹ̀kọ Yorùbá. Bí ìgbà tí ènìyàn ń fèdè fọ̀ ni àgbékalẹ̀ ewì àwọn akéwì àpilẹ̀kọ ilẹ̀ Ẹ̀gbá yìí láti kà fún àwọn tí kì í bá ṣe ọmọ bíbí, tàbí ẹni tó dàgbà ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá tó sì létí èdè. Ìyapa lórí ìlànà ti ó yẹ láti tẹ̀lé fún kíkọ ewì tó farapẹ́ “ìfèdèfọ̀” tún jẹ́yọ nínú àṣàyàn ewì àpilẹ̀kọ àwọn akéwì Yorùbá, ilẹ̀ Ẹ̀gbá bí: Ṣóbọ̀wálé Ṣówándé (Ṣóbọ̀ Aróbíodu), Ṣómújì, Oyèṣílẹ̀ Kẹ̀ríbo àti bẹ́è bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, àṣàyàn ewì àpilẹ̀kọ Ṣóbọ̀wálé Ṣówándé tí a mọ̀ sí (Ṣóbọ̀ Aróbíodu) tí Ọlátúnjí (1979) tẹ̀ jáde ni a yẹ̀ wo nínú ṕep̀a yìí. Ohun pàtó tó jẹ́ àfojúsùn wa nínú pépà yìí ni àgbéyẹ̀wò ìgbéǹde àti ìdàgbàsókè ewì àpilẹ̀kọ láwùjọ Yorùbá nípa àmúlò ẹ̀ka-èdè Ẹ̀gbá àti àwọn àbùdá ìyàtọ̀ tó hànde nínú ewì àpilẹ̀kọ rẹ̀ tó farasin fún kíkà yó ṣe ní ìtumọ̀ dé ààyè kan. Lóòtọ́ ni àyípadà ń dé bá ewì àpilẹ̀kọ ní ilẹ̀ Yorùbá, nípa àwọn kókó-ọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ àfidáṣà ìgbàlódé tó ń jẹyọ lọ́tunlọ́tun àti látìgbàdégbà, àmọ́ a kò tún tí ì rí àwọn akéwì ìgbàlódé Yorùbá tó ṣẹ̀dá ewì tàbí ṣàmúlò ẹ̀ka-èdè Yorùbá mìíràn láti fẹwà ẹ̀ka-èdè Yorùbá dárà bí ẹní-ń-fèdè-fọ̀ bí àwọn akéwì àpilẹ̀kọ ilẹ̀ Ẹ̀gbá. Tíọ́rì èdè-ajẹ́mádùúgbò (Nativism) ni àtẹ̀gùn tí a lò fún títúmọ̀ àwọn wúnrẹ̀n ẹ̀ka-èdè Ẹ̀gbá tó takókó nínú àṣàyàn ewì Ṣóbọ̀ tí a lò. Nípa àkíyèsí, àlàyé àti ìtúpalẹ̀ àṣàyàn ewì tí a gbéyẹ̀wò, a wòye pé, àmúlò ẹ̀ka-èdè Yorùbá fún kíkọ ewì àpilẹ̀kọ lè ṣokunfa ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀ka-èdè. Bákaan náà, ó tún lè ran gbígbọ́ èdè abínibí àti kíka ewì àpilẹ̀kọ pẹ̀lú ẹ̀ka-èdè geerege fún àwọn ọmọdé. Síwájú sí i, ó tún lè dènà ewu tó rọ̀ mọ́ kí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá kú àkúrun nípa bí ọ̀wọ́ àwọn àgbàlagbà tó gbọ́, tó sì ń sọ wọ́n ti wọn ń papòdà láti ìgbàdégbà láìśí akitiyan fífi irúfẹ́ ẹ̀ka-èdè bẹ́ẹ̀ lé àwọn ọmọ lọ́wọ́ fún ìtẹ̀síwájú.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÌṢÒRO ÌṢÀMÚLÒ Ẹ̀KA-ÈDÈ NÍNÚ EWÌ ÀPILẸ̀KỌ YORÙBÁ: EWÌ ṢÓBỌ̀WÁLÉ ṢÓWÁNDÉ BÍ ÀPẸẸRẸ. (2026). Láàńgbàsà, 23(1), 119-128. https://doi.org/10.5281/zenodo.20775993