ÌHÀ ÌJỌBA SÍ ÌṢÀMÚLÒ ÒFIN ÌGBÁṢÀ YORÙBÁ LÁRÚGẸ́ LÓRÍ ERÉ ONÍṢE ÀTI ÌGBÓHÙNSÁFẸ́FẸ́
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20776240Keywords:
Ìhà ìjọba, ìṣàmúlò òfin, ìgbásàlárugẹ, Yorùbá, eré oníṣeAbstract
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ pọ̀ lọ jaburata lórí òfin ajẹmáṣà tí ó yẹ kí ó ṣe agbátẹrù ìgbásà Yorùbá lárúgẹ, síbẹ̀ kò tí ì sí àrídájú pé ìjọba àti àwùjọ ń ṣe àmúlò àwọn òfin yìí fún ìgbélárugẹ ìdáàbò bò àti ìṣàmúlò àwọn òfin wọ̀nyí fún ìdàgbàsókè àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Àpilẹ̀kọ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ránpẹ́ pẹ̀lú ìṣámúlò tíọ́rì ìfojú àṣà ìbílẹ̀ wò. Àṣà Yorùbá àti òfin ìgbáṣàlárugẹ tí ìjọba Nàìjíríà ṣe ní 1988 tí wọn pín káàkiri ní 1989 (Cultural policy for Nigeria, National Council for Arts & Culture, Abuja, 1988) láti gbé àṣà orílẹ̀ èdè lárugẹ fún ìdàgbàsókè àwùjọ ní a ti fa èròjà ìwádìí jáde. Lára àbájáde ìwádìí yìí ni pé ìjọba tí ó ṣe òfin àti àwùjọ tí a ṣe òfin fún kò náání àwọn òfin ìgbàṣàlárugẹ wọ̀nyí, ará ìlú náà kò sì bìkítà àtunbọ̀tán àṣà Yorùbá. Iṣẹ́ yìí fìdí múlẹ̀ pé ṣíṣe agbátẹrù fún àṣà ilẹ̀ wa yóò ṣe àtúnṣe sí àṣà tí ó doríkodò tí yóò sì ṣe atọ́nà fún ìlọsíwájú àṣà àti ètò ìṣúná orílẹ̀ èdè yìí.
