IPA TÍ ÀWÙJỌ Ń KÓ LÓRÍ ỌMỌ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ: ṢÍṢE ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN ỌPẸ́YẸMÍ ÌGBẸ̀YÌNÁDÙN TÍ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ KỌ

Authors

  • Christiana Táíwò BABÁTÚNDÉ Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20776595

Keywords:

Ipa, Àwùjọ, Ọmọ, Ilẹ̀ Yorùbá, Ìwé Ìtàn-Àròsọ

Abstract

Ipa tí àwùjọ ń kó lórí ọmọ kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ọ̀nà méjì sì ni ipa tí a ń wí yìí lè jẹ́. Ó le jẹ́ ipa rere tàbí ipa burúkú. Ìwà àwọn ènìyàn sì ní yóò sọ irú ipa tí àwùjọ yóò kó lórí ọmọ. Èróńgbà iṣẹ́ yìí ní láti wo ipa tí àwùjọ kó lórí ọmọ bí ó ti farahàn nínú ìwé eré onítàn Ọpẹ́yẹmí Ìgbẹ̀yìnádùn. Nínú iṣẹ́ yìí, a ó ṣe àlàyé lórí àwùjọ ọmọnìyàn, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa ọmọ àti pàtàkì ọmọ láwùjọ Yorùbá. Tíọ́rì soṣiọ́lọ́jì lítíréṣọ̀ ní a gbé iṣẹ́ yìí kà. A pinnu láti lo tíọ́rì náà nítorí pé kókó-ọ̀rọ̀ tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí jẹ mọ́ àwùjọ. Àbájáde iṣẹ́ yìí fihàn pé ipa tí àwùjọ kó lórí ọmọ ṣe pàtàkì nítorí pé inú àwùjọ ní ọmọ wà. Ìdí nìyí tí gbogbo ènìyàn ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe rere fún ọmọ kí gbogbo ènìyàn inú àwùjọ sì pawọ́pọ̀ láti tọ́ ọmọ, kí ọjọ́ ọ̀la ọmọ àti àwùjọ lè dára. Iṣẹ́ yìí gúnlẹ̀ pé ìwé eré onítàn Ọpẹ́yẹmí Ìgbẹ̀yìnádùn tí a ṣe àmúlò ṣe rẹ́gí pẹ̀lú kókó-ọ̀rọ̀ tí a gbé yẹ̀wò nínú iṣẹ́ yìí.

 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

IPA TÍ ÀWÙJỌ Ń KÓ LÓRÍ ỌMỌ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ: ṢÍṢE ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN ỌPẸ́YẸMÍ ÌGBẸ̀YÌNÁDÙN TÍ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ KỌ. (2026). Láàńgbàsà, 23(1), 146-158. https://doi.org/10.5281/zenodo.20776595