ÌKÍNI: PÀÀPIN ÌWÀ ỌMỌLÚÀBÍ LÁWÙJỌ YORÙBÁ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20776730Keywords:
Ìkíni, pààpin, ọmọlúàbí, tíọ́rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wò, ọ̀tọ̀lórìnAbstract
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọmọlúàbí láwùjọ Yorùbá, a kò lè fi ọwọ́ rọ́ àṣà ìkíni sẹ́yìn. Àwọn àgbà ní: “ibi kíkí ni ọmọlúàbí parí sí” tàbí “ibi kíkí ni ọmọlúàbí ti bẹ̀rẹ̀”. Nítorí náà, átíkù yìí ṣe ọ̀rínkínniwín àlàyé lórí àkọ́lé yìí: “Ìkíni: Pààpin Ìwà Ọmọlúàbí Láwùjọ Yorùbá”. A dágbá lé àkọ́lé yìí nítorí pé a róye pé iná àṣà ìkíni láwùjọ Yorùbá ti ń jó àjórẹ̀yìn. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Yorùbá ní òde-òní ni kò mọ bí a ti ń kíni, wọn kò mọ ìkíni tó bá ẹni, àkókọ̀, iṣẹ́, ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan mu. Ìdí rèé tí a fi ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí àṣà ìkíni Yorùbá lẹ́nu àwọn àgbààgbà àti nínú àwọn ìwé àpilẹ̀kọ lónírúurú. Tíọ́rì ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-láwùjọ-wò ni a fi tukọ̀ iṣẹ́ yìí. Gbangba ló dájú pé lára àwọn kókó tí àwọn agbátẹrù tíọ́rì ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-láwùjọ-wò ti ọ̀wọ́ tó tẹ̀lé Taine fúnka mọ́ ni àyípadà àṣà àti bí àṣà ṣe ń mú ìlọsíwájú bá àwùjọ sí. A yànnàná pàtàkì ìkíni láwùjọ Yorùbá, a wo àbùdá ìkini Yorùbá, a pín ìkíni Yorùbá sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, a wo àṣà ìkíni àtọ̀húnrìnwá tó dàpọ̀ mọ́ ti Yorùbá, a kò ṣàì ṣe àfiwé àṣà ìkíni ayé-àtijọ́ àti tòde-òní, a wo àǹfààní, àléébù, èèwọ̀ àti àwọn òwe tó rọ̀ mọ́ àṣà ìkíni Yorùbá, kí a tó wakọ̀ ìwádìí wa gúnlẹ̀. Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé àyípadà ńlá ti dé bá àsà ìkíni láwùjọ Yorùbá látàrí ìlàjú àlàsódì àti àgbàsódì ẹ̀sìn àjòjì. Bákan náà, àbájáde ìwádìí yìí sì tún tọ́ka sí àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà kíni àti bí ó ṣe yẹ kí wọ́n máa kíni láwùjọ Yorùbá.
