ÌGBÀGBỌ́ YORÙBÁ ÀTI OJÚ ÀMÚWÁYÉ ÀWỌN ÒṢÈRÉ OLÓRIN NÍPA ORÍ NÍ ÀWÙJỌ YORÙBÁ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20776966Keywords:
ojú àmúwayé, orí, òṣèré olórin, àwùjọ YorùbáAbstract
Àṣàmọ̀
Méjì ni ọ̀rọ̀ orí pín sí ní àwùjọ Yorùbá, orí inú àti orí òde. Orí inú ni èyí tí ó wà nínú nígbà tí orí òde sì jẹ́ èyí tí ó wà ní ìta tí ọrùn gbé dúró. Yorùbá gbágbọ́ nípa orí púpọ̀. Wọn kì í fi ọ̀rọ̀ nípa orí ṣe àwàdà rárá. Àlàfo àyè tí ìṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí fẹ́ dí ni pé, kò sì irúfẹ́ ènìyàn tí ó wa láwùjọ tí kò mo bí ọ̀rọ̀ orí ṣe jẹ́ pàtàkì tó. Ìdí nìyí tí a fi wòye pé kí a gbíyànjú láti fi ojú tí àwọn òǹkọrin tàbí apohùn fi wo ọ̀rọ̀ orí hàn fáráyé láwùjọ Yorùbá. A ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn òǹkọrin díẹ̀ bí i Síkírù Ayìndé Barister, Kolinton Àyìnlá, Saheed Òṣùpá àti Sunny Ade àti èro wọn nípa orí, a tún wo àwọn òwe Yorùbá díẹ̀ tí o sọ̀rọ̀ nípa orí. Bákan náà ní a gbìyànjú láti jẹ́ kí á mọ ìgbágbọ́ Yorùbá nípa orí. À fìdí ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa orí múlẹ̀ nínú àdúrà tí wọ́n máa ń gbà wí pé, orí ló gbe ológún ẹrú lọ́jọ́sí, òun náà ló gbe ọlọ́gbọ̀n ìwọ̀fà, kí Elédùmàrè jẹ́ ki orí tàwọn náà gbè wọ́n.
