ÀTÚNYẸ̀WÒ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÒKÈ (SOO) NÍ Ẹ̀KA ÈDÈ ARIGIDI

Authors

  • Samuel Obalolu OKE University of Ibadan, Nigeria Author
  • Olaide Ridwan JIMOH University of Ibadan, Nigeria Author

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.20757033

Keywords:

Sílébù olóhùn òkè, àbùdá iye, Ìrísí, Arigidi

Abstract

Sílébù Olóhùn Òkè (SOO) ni wúnrẹ̀n gírámà tó máa ń jẹyọ láàárín olùwà àti àpólà ìṣe nínú Yorùbá Àjùmọ̀lò àti àwọn ẹ̀ka èdè rẹ̀, èyí tí Arigidi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀ka èdè náà. Ìmọ àtijọ́ lórí SOO ní ẹ̀ka èdè Arigidi ni pé ó jẹ́ atọ́ka afànámọ́mìí tàbí wúnrẹ̀n tí ó ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí tuntun tí a yànnàná rẹ̀ nínú bébà yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wúnrẹ̀n náà ń ṣàfihàn àbúdà iye olùwá nínú gbólóhùn ní. Torí náà, ìrísí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní SOO ní èdè Arigidi ní. Ìrísí àkọ́kọ́ ní ‘á’, èyí tí ó máa ń jẹyọ nígbà tí olùwà inú gbólóhùn bá jẹ́ ẹyọ. Ìrísí rẹ̀ kejì sì ni ‘wá’, tí ó máa ń jẹyọ nígbà tí olùwà bá jẹ́ ọ̀pọ̀. 

Downloads

Download data is not yet available.

References

Downloads

Published

2025

How to Cite

ÀTÚNYẸ̀WÒ SÍLÉBÙ OLÓHÙN ÒKÈ (SOO) NÍ Ẹ̀KA ÈDÈ ARIGIDI. (2026). Láàńgbàsà, 25(1), 1-13. https://doi.org/10.5281/zenodo.20757033