ÀWỌN ÒǸKỌ̀TÀN ÌTÀN-ÀRÒSỌ YORÙBÁ LÓRÍ ÌBÁṢEPỌ̀ TÓ WÀ LÁÀÁRIN OJÚṢE ÒBÍ ÀTI ÀÌSÁÀBÒ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20757224Keywords:
Ètò Ààbò, Àìsáàbò, Ìdàgbàsókè, Ìtàn-Àròsọ, orílẹ̀-èdè NàìjíríàAbstract
Ọkan lára ìṣòro tó ń gbógun ti ìdàgbàsókè àwùjọ wa ni àìsáàbò jẹ́, àìsáàbò yìí sì dàbí jẹjẹrẹ tó ń jẹ orílẹ̀-èdè Nàìjìríà díẹ̀díẹ̀. Àwọn onímọ̀ lẹ́ka gbogbo a máa fojú eréfèé wo ọ̀rọ̀ ètò ààbò nípa dídárúkọ àìríṣẹ́ṣe, ìjákulẹ̀ ìjọba, èètò ìdájọ́ tó mẹ́he̩ àti àwo̩n yòókù bí i rè̩ gẹ́gẹ́ bí okùnfà àìsáàbò ṣùgbọ́n amúkùn-ún ẹrù rẹ wọ́ lọ̀rọ̀ náà, ó ní òkè lẹ ń wò, ẹ kò wo ìsàlẹ̀. Nítorí náà, iṣẹ́ ìwádìí yìí tọ́ka sí ojúwòye àti ìhà tí àwọn òǹkọ̀tàn ìwé ìtàn-àròsọ Yorùbá márùn-ún kọ sí ọ̀rọ̀ ojúṣe òbí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọ̀nà àbáyọ sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà; Atótó Arére, Ìrìnàjò Ìfẹ́, Ayé Dayé Obìnrin, Ọmọ Ẹni ò Ṣèdí Bẹ̀bẹ̀rẹ̀ ai Ṣóoróyè. Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣàmúlò tíọ́rì ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ wo lítírés̩ò̩ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá òdiwọ̀n. Ìwádìí fi hàn pé àwọn òǹkọ̀tàn ìwé ìtàn-àròsọ Yorùbá rí ojúṣe òbí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan gbòógì lára àwọn ọ̀nà àbáyọ sí àìsáàbò láwùjọ. Wó̩n ṣe àgbékalẹ̀ ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín ojúṣe òbí àti ìwà àìtọ́ tó ń ṣe okùnfà àìsáàbò. Is̩é̩ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ì-báni-dáa-báni-débẹ̀, ẹ̀kọ́ àkọ́yege, jíjẹ́ àwòkọ́ṣe rere àti ìmúdúró ìgbéyàwó gan-an tó jẹ́ ojúṣe òbí ni ọ̀nà àbáyọ àkọ́kọ́ fún ìwà àìtọ́ láwùjọ. Iṣẹ́ ìwádìí yìí wá dá a lábàá pé ẹ̀kọ́ nípa ojúṣe òbí yẹ kó wà nínú kò̩ríkúlọ́ọ̀mù ilé ẹ̀kọ́ girama, òfin tó wà nílẹ̀ nípa ṣíṣe àti àìṣe ojúṣe òbí gbọ́dọ̀ múlẹ̀ láti dènà àìsáàbò tó ń pagi dínà ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.
