ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌJẸYỌ ATỌ́KA ÌYÍSÓDÌ NÍNÚ ORÚKỌ ÀBÍKÚ
DOI:
https://doi.org/10.5281/zenodo.20757581Keywords:
Àpólà ìṣe, Awẹ́-gbólóhùn, Gbólóhùn, Ìyísódì, Orúkọ ÀbíkúAbstract
Káríayé ni ìyísódì jẹ́ nínú èdè ọmọnìyàn. Kì í ṣe ohun tuntun pé ìyísódì máa ń jẹ yọ nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ Yorùbá bíi àbíìkọ́, àkọ́ọ̀gbà, àwíìgbọ́, àfọ̀ọ̀gbà, abbl yàtọ̀ sí nínú gbólóhùn. Atọ́ka ìyísódì yìí náà ni ó tún ń jẹ yọ nínú àwọn orúkọ àbíkú Yorùbá kan, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tí ì ṣisẹ́ lórí rẹ̀ rí. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò lórí ìyísódì tó máa ń jẹ yọ nínú àwọn orúkọ àbíkú Yorùbá kan. Ètò girámà oníwọ̀nba-èròja (minimalist program) ti Chomsky (1995, 1998, 2002) ni isẹ́ yìí gùnlé fún ìtupalẹ̀ ẹ̀hun ìyísódì nínú àwọn orúkọ àbíkú Yorùbá náà. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé pé ọ̀nà mẹ́ta ni ìyísódì ń gbà jẹ yọ nínú àwọn orúkọ àbíkú oníyìsódì bí a bá ṣe ìtúpalẹ̀ ìhun àwọn orúkọ àbíkú Yorùbá bẹ́ẹ̀: orúkọ àbíkú oníyìsódì alápòólà ìṣe, orúkọ àbíkú oníyìsódì aláwẹ́-gbólóhùn, àti orúkọ àbíkú oníyìsódì odindi gbólóhùn. Iṣẹ́ yìí tún jíròrò lórí orúkọ àbíkú oníyìsódì kan tí wúnrẹ̀n ìyísódì wọn kò fojú hàn nínú ìhun òke àwọn orúkọ àbíkú oníyìsódì bẹ́ẹ̀ àyàfi bí a bá tanná wo ìhun ìpìlẹ̀ (nínú ìtúpalẹ̀ àti àlàyé ajẹmọ́-sẹ̀máńtíìkì) wọn. Lẹ́yìn náà ni àpilẹ̀kọ yìí kádìí ọ̀rọ̀ nílẹ̀ nípa ṣíṣe àfihàn àgbéjáde ìhun àwọn orúkọ àbíkú oníyìsódì Yorùbá náà nínú èyí tí wúnrẹ̀n ìyísódì (IY) ti yan àpólà àsìkò (APAS) tàbí àpólà ìṣe (APIṢ) gẹ́gẹ́ bí àfikún láti ṣe àgbeyọ ìhun rẹ̀.
